Yoruba

Mo rin irin ajo lo si igberiko ni ojio isegun , ohun ti mo ri bamileru gidigidi. Awa agbagba marun laa joko ni iwaju oko kekere ti won npe ni ‘minibus’ ti a wo.  Awon meji lori ijoko dereba (awako), eni meji ni ori ijoko  eero legbe dereba (awako), eni kan run ara re mo opa oko ti won npe ni ‘gear’ oko naa. Okunrin  ti o joko legbe mi ni apa otun  feere fun mi paa.

Inu bi mi gidigidi nitori wipe eruku ile bomi, gbogbo eti sokoto kaaki(jeans) ti mowo ni igbe ati ito yii nibiti ati duro leba ona.

Nigbati a de ibiti a nlo lehin wakati marun pelu ibinu gbogbo bi irin ajo naa ti lo, awon ti a lo ba lalejo ko tile damimo moo.  Emi fun ra mi ko tile mo bi eruku ti kun mi to, afi igba ti won fun mi ni aso inu oju pelebe lati fi nu oju mi (kinto bere eto ti a lo see) – moo nu oju mi pelu aso inu oju naa, won si fi suuru  so fun mi pe mo ni lati nu irun ori mi bakanna- irun ori mi naa pon fun ekuru ile. Sebi oro to ba koja ekun, erin la ma fi nrin. Sugbon ni akoko yi mowa loju ina , eyin obinrin, eyin alabasisepo mi, ema ro wipe mowa ni isinmi o.

Lorokan sa, won mu mi lo si ibi ti won  fi awon ti won sa asala fun emi won (ti a npe ni refugee)pamo si, mo si ba awon obinrin lati ile Liberia pade. Iyalenu lo je fun mi nigba ti awon obinrin agbalagba ti won to egbe iya mi sunmo mi, ti won si so  awon  orisirisi oro fun mi, awon oro bii:  awon okunrin marun ba mi lopo ni tipatipa…., nise ni idi mi ma nseje ni gbogbo igba ti oko mi baa ba mi lajosepo…., nkan osu mi kan ma nda yaa ni laiduro……, oorun to njade lara mi ko daa rara….., Ile omo mi ti fe yoo jade…..,orisirisi  awon oro beebe.

Ohun ti mo kan nso fun won niwipe ….e seun ma, e se pupo, eyin nko maa,,,, talo fi tipatipa ba yin lajosepo… e pele. Ni akoko kan , ikan lara awon olori egbe awon obirin wonyi  naa busekun, osi wipe “woo iwo, omo mi loje! Emi ni iya re. emi le kawe, omo mi ko le kawe, oo ri mi bayi , ko si oluranlowo.

Ko si ohun toku ti mo fe se ju kin busekun lo. Je ki nso fun e, gbogbo awa ti awa nbe labusekun. O ba mi ninu je gidigidi